Odù Ifá Ògbè Ogúndá
Odu Ifá Ògbè Ogúndá
Narrator: bàbáláwo Fábùnmi Ṣówùnmí
Gbengbelekú performed a divination wherever he wanted, and he was the one who divined for Igún¹, Elédùnmarè’s first-born son, on the day he fell ill and his father was solely preoccupied with how to heal him.
〈¹ Igún, the name of the protagonist that denotes a vulture, a bird of prey.〉
Igún, the first-born son of Elédùnmarè, who is Agọ̀tún, the one who turns rain into a source of wealth.
Elédùnmarè did everything in his power to help his son but to no avail. Reaching the point of exhaustion, he opened the door to ayé for him so he could go live there.
Tótó Ìbarà was the one who performed a divination for Ọ̀rúnmìlà as he was crying over the absence of luck in his life. He went to consult his priest to find out if he would have enough money to create a home and raise his children.
This was the reason he went for a spiritual consultation with Ifá. His priests gave him spiritual guidance, instructing him to perform an ẹbọ with five chickens. If he continuously performed the ẹbọ for five days, all the desired wealth would come to him.
He had to sacrifice chickens to his Ẹlẹ́dàá, each one separately, every day for five consecutive days. He had to remove the intestines of every sacrificed animal, put them into a calabash, cover them with red palm oil, and take them to an intersection. He was allowed to eat the meat himself or with the members of his family. On his way to the intersection, Ọ̀rúnmìlà had to sing loudly and melodiously: “May luck come to me! May luck come to me!” He had to repeat this ritual for five days.
Ọ̀rúnmìlà followed the spiritual instructions he received and began to perform the ẹbọ. He sacrificed chickens and took their intestines coated in red palm oil to the intersection. He placed the offering onto the ground and prayed for luck to come to him.
Opposite the intersection was a forest that was a home to Igún, the son of Elédùnmarè. Every time Ọ̀rúnmìlà placed the offering at the intersection and left, Igún came and ate it.
Igún, the son of Elédùnmarè, had five illnesses: his head, arms, and chest were afflicted, and he had a hump on his back as well as paralysed legs.
On the first day when Igún ate Ọ̀rúnmìlà’s offering, he was shocked to find that he was cured of the illness that affected his head. The following day, Ọ̀rúnmìlà repeated the ritual and again brought ẹbọ to the intersection, unaware of the fact that someone ate his offering. As soon as Ọ̀rúnmìlà left, Igún reappeared and ate the offering. Thereafter, he was suddenly able to easily outstretch his arms. On the third day, Ọ̀rúnmìlà continued the process and brought a new offering to the intersection. Just as he placed it, Igún came crawling back and ate it. As soon as he consumed it, the swelling on his chest went down. On the fourth day, Ọ̀rúnmìlà took his ẹbọ to the intersection, singing along the way: “May luck come to me! May luck come to me!” As soon as he placed it down, Igún reappeared and consumed it. The hump on his back disappeared in an instant. On the fifth day, Ọ̀rúnmìlà took his ẹbọ to the intersection to finalise the offerings. On his way, he was singing the same song as the previous days. As soon as he placed the ẹbọ onto the ground, Igún appeared and ate it. At the dawn of the sixth day, his crippled legs were revitalised, and he was able to walk anywhere. This is how Igún was healed of his maladies.
Delighted over the turn of events, Igún stood up and went to ọ̀run to meet Elédùnmarè. He instantly noticed his son was healthy and asked who had healed him.
Igún immediately told Elédùnmarè everything that transpired. He said Ọ̀rúnmìlà had brought the offerings and added that he had been singing the same refrain while doing so: “May luck come to me! May luck come to me!”
Elédùnmarè said he would reward this person generously. He took four àdo² and gave them to Igún to take them to Ọ̀rúnmìlà in ayé. These were the àdo of prosperity (bringing wealth and money), fertility, longevity, and patience.
〈² Àdo, a term that denotes a gift, mercy.〉
Igún told Elédùnmarè he did not know how to reach Ọ̀rúnmìlà’s home, but his father instructed him to ask people for direction upon his arrival to ayé, and they would show him the way. Before Igún left ọ̀run, Elédùnmarè told him that Ọ̀rúnmìlà might choose only one of the four àdo, and the remaining three had to be brought back to him.
Igún returned to ayé with four àdo and went straight to Ọ̀rúnmìlà to show them to him. Ọ̀rúnmìlà was very surprised.
Confused and unsure, he ordered his sons to be summoned so that he could ask them for advice on which àdo to choose. They advised him to select the àdo of longevity so that he would live long.
Ọ̀rúnmìlà then summoned his wives to listen to their advice, and they urged him to choose the àdo of fertility so they could bear many more children.
Ọ̀rúnmìlà summoned his brothers so they could advise him on which àdo to choose, and they told him to select the àdo of prosperity in order to ensure wealth and money.
Then Ọ̀rúnmìlà ordered to summon his best friend. That was Èṣù. When Èṣù came, Ọ̀rúnmìlà told him everything that happened and asked him for advice on what choice to make. The ever-resourceful Èṣù posed the following questions to Ọ̀rúnmìlà:
– Which àdo did your sons advise you to choose?
Ọ̀rúnmìlà said:
– The àdo of longevity.
Èṣù told him not to select this àdo because no person could overcome death, and he reminded him of the fact that even those who managed to lead a long life inevitably died at some point.
Then Èṣù asked:
– Which àdo did your wives advise you to choose?
Ọ̀rúnmìlà said:
– The àdo of fertility.
Èṣù advised him against selecting this àdo because he already had children. He then asked:
– What about your brothers? Which àdo did they advise you to choose?
Ọ̀rúnmìlà answered:
– The àdo of prosperity.
Èṣù advised him against selecting this àdo because if he were to become rich, he would have to alleviate the poverty of the entire family, adding that if his brothers wanted to prosper, they should get to work.
Ọ̀rúnmìlà then asked Èṣù which àdo to choose. Èṣù advised him to select the àdo of patience because his lack of patience prevented him from achieving the desired results in the past. As long as Ọ̀rúnmìlà followed this advice and chose the àdo of patience, all of the other àdo would eventually belong to him as well. Ọ̀rúnmìlà heeded Èṣù’s advice and selected the àdo of patience, returning the remaining three to Igún.
Ọ̀rúnmìlà’s sons, wives, and brothers were not happy with his decision.
Igún headed back to ọ̀run with the three remaining àdo to return them to Elédùnmarè. But soon after they left, the àdo of wealth asked him:
– Where is Patience?
Igún said that it had stayed with Ọ̀rúnmìlà.
Wealth then said that it would return to where Patience was because it only existed next to Patience. Igún said that was unacceptable and that Wealth had to return with him to ọ̀run. Wealth insisted that it only existed where Patience was and that it had no reason to go back to ọ̀run. It soon vanished from Igún’s hand and joined Patience at Ọ̀rúnmìlà’s home.
Fertility asked Igún about Patience as well, and he said that it was at Ọ̀rúnmìlà’s home. Fertility responded that it only existed where Patience was. It got up and soon joined Patience at Ọ̀rúnmìlà’s home.
Longevity also asked Igún where Patience was. He said it was at Ọ̀rúnmìlà’s home, and Longevity went to join Patience as well.
As Igún arrived to ọ̀run, Elédùnmarè asked him where the remaining three àdo were. He explained that all three had wanted to stay at Ọ̀rúnmìlà’s home with Patience and that he was about to return to ayé to find them and bring them back to ọ̀run. Elédùnmarè said there was no need to do that because all àdo belonged to the one who chose Patience. Those who are patient will have Longevity and Fertilty: they will be fertile and lead a good life, and they will prosper as well.
Things turned out well for Ọ̀rúnmìlà in the end, and with all these gifts, he became the king of Kétu. He lived a prosperous and long life with all the àdo. He was so wealthy that he built houses all over the world.
Happy with his achievements, he rode his horse singing: “I got the àdo of prosperity, I got the àdo of longevity, and I got the àdo of patience.” He danced and rejoiced, exalting his priests and his friend Èṣù.
Source: Sàlámì, S. and Ribeiro, I.: Ešu in ureditev univerzuma. Podčetrtek, Duhovna skupnost oriš – energij narave, 2015.
Odu Ifá Ògbè Ogúndá
Narrator: bàbáláwo Fábùnmi Ṣówùnmí
Gbengbelekú dá níbi tí ó wùn-ún
A d’ífá fún igún tí nṣe àkọ́bí Elédùnmarè
Agọ̀tún a tẹ́ní ọlá S’éjí
Ó ntàrùn gbọ̀gbọ̀
Ó n tajú àtí dìde
Elédùnmarè sa gbogbo agbára ẹ̀,
Ṣùgbọ́n igún kò sàn.
Ó wá ṣílẹ̀kùn ayé fún-un,
Wípe kí ó máa lọ gbé òde ayé;
Tótó ìbàrà òún ló ṣé Ifá fún Ọ̀rúnmìlà,
Ifá nsunkún aláì rí ire;
Njẹ́ òún lè ní owó,
Kí òún róun tọ́ju àwọn ọmọ tí òún bí;
Ki òún sì tún kọ́lẹ́.
Ni ó tóri ẹ̀ d’ífá
Aláwo rẹ̀ ní kí ó ní rú obí adiẹ̀ márùn-ún,
Wípé tí ó bádi ọjọ́ karùn ire tí o nwá yóò tó o lọ́wọ́
Kí ó máa pá ni ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ojojúmọ́ bọ ẹlẹ́dàá rẹ̀
Kí ó máa kó ìwọ́rọ́kùn rẹ̀ sínú igbá
Kí ó da epo le lórí,
Kí ó máa gbé lọ sí oríta mẹ́ta.
Kí òún àti àwọn ẹbí sì máa jẹ adìẹ naà;
Tí ó bá tí ngbé ìwọ́rọ́kùn adìẹ yìí lọ́,
Kí ó máa lọgun kọrin ki òún ríre; kí òún ríre
Títí yóò fi dé oríta.
Yóò ṣe eléyì fún ọjọ́ màrùn-ún
Ọ̀rúnmìlà ṣe ètùtù;
Báyìí ni Ọ̀rúnmìla ṣe bẹrẹ sí ni rú ẹbọ
Tí yóò sì kó ìwọ́rọ́kùn rẹ̀,
Lọ oríta, tí o bá dé oríta;
Yóò máa wá da epo síi.
Tí ó bá da epo síitan,
Yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni gbàdúrà wípé, kí òún ríre o,
Inú igbó tí ó wà níwájú oríta yìí ni;
Igún ọmọ Elédùnmarè, wà,
Bí Ọ̀rúnmìlà ṣe ngbé ẹbọ sílè,
Bí Ọ̀rúnmìlà bá gbé ẹbọ sílẹ̀, a yípadà;
Ní igún yóò bọ́ síbẹ̀,
Tí yóò sì kó ẹbọ náà jẹ.
Igún ọmọ Elédùnmarè, àrùn márùn-ùn wà,
Tí ó nbá jà, ni ara, orí, apá, àyà, iké, ẹsẹ̀.
Ní ọjọ́ kini, tí ó jẹ ẹbọ Ọ̀rúnmìlà,
Ní àrùn yìí kò tún bá jà mọ́; ẹnu yà á,
Ní ọjọ́ keji Ọ̀rúnmìlà tún gbé ẹbọ yìí lọ sí oríta,
láì mọ̀ wípé, ẹnì kan njẹ ẹbọ rẹ̀.
Bí ó ṣe yípadà ni igún bọ́ síbẹ̀,
Tí ó jẹ ẹbọ Ọ̀rúnmìlà,
Apá igún méjéèjì tí kò ṣe náà tẹ́lè náà.
Nígbà tí ó jẹ ẹbọ yìí tán;
Nígbàtí ó dí ọjọ́ kẹta Ọ̀rúnmìlà,
Tún gbe ẹbọ yìí lọ sí oríta.
Bí o se yípàdà ni igún bọ́ síbẹ̀,
Tí o kó ẹbọ Ọ̀rúnmìla jẹ;
Àyà igún tí o wú tẹ́lẹ̀ bá fọn,
Nígbà tí ó jẹ ẹbọ Ọ̀rúnmìlà tán,
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin;
Ọ̀rúnmìlà tún gbé ẹbọ rẹ̀ lọ sí oríta,
Ó n lọgun kí òún ríre o, kí òún ríre.
Bí ó ṣe gbẹ́bọ sílẹ tán,
Ni Igún tún bọ́ síbẹ̀, tí ó kó ẹbọ jẹ.
Iké tí ó wà lẹ́yìn Igún kúrò,
Bí ó ṣe jẹ ẹbọ yìí tán,
Nígbà tí ó dí ọjọ́ karùn-un
Ọ̀rúnmìlà tún gbe ẹbọ rẹ̀ lọ sí oríta
Ọ́ n lọgun kí òún Ọ̀rúnmìlà ríre o,
Bi ó ṣe gbẹ́bọ sílẹ̀ tán,
Ní Igún tún bọ síbẹ̀ tí ó kó ẹbọ jẹ;
Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹfà máa mọ́,
Ẹsẹ̀ igún méjèèjì tí kò ṣe rìn náà;
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn, àrùn tí ó n báa jà parẹ́,
Ó bá gbéra, Ó lọ sóde ọ̀run ní ọ̀dọ̀ Elédùnmarè;
Elédùnmarè ríi wípé, igún tí sàn,
Ó wá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wípé, tani ó wò ọ́ sàn?
Ó bá ṣí, Ó kẹ́jọ́, Ó rò fún Elédùnmarè,
Ó ní, òún mọ̀ ẹni náà ṣùgbọ́n Ọ̀rúnmìlà ni orúkọ rẹ̀ n jẹ́.
Àtí wípé bí ó ṣe ngbébọ lọ sí oríta ni ó n lọgun.
kí òún rí ire o, kí òún rí ire o.
Elédùnmarè ní, òún yóò dá ẹni náa ni ọlá,
Elédùnmarè kó àdó mẹ́rin fún igún;
Wípé, kí ó kó lọ bá Ọ̀rúnmìlà lóde ayé,
Igún fún Elédùnmarè lésì wípé;
Òún kò mọ́ ilé Ọ̀rúnmìlà,
Elédùnmarè ní, tí igún bá tí délé ayé, kí ó béérè;
Àwọn ènìyàn yóò filè Ọ̀rúnmìlà han igún,
Ó wá sọ fún igún wípé, ẹyọ kan ṣoṣo nínú
Àwọn àdó mẹ́rin yẹn ni kí Ọ̀rúnmìlà mú,
Ki Igún sì kó éyí tí ó kù padà wá sóde ọ̀run.
Àwọn àdó náà;
Àdó owó, Àdó ọmọ;
Àdó àrìkú, àdó sùúrù.
Igún sì padà wá sóde ayé.
Bí ó ṣe délé ayé tán,
Ó gbá ilé Ọ̀rúnmìlà lọ;
Nígbà tí ó délé Ọ̀rúnmìlà,
Ó kó àwọn àdó náà sílẹ̀ fún Ọ̀rúnmìlà
Ẹnu ya Ọ̀rúnmìlà.
Ó ránṣẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ́,
Látí gbá àmọ̀ràn nípa èyí tí ó tọ́.
kí ó mú nínú àwọn àdó mẹ́rẹ́ẹ̀rin.
Àwọn ọmọ Ọ̀rúnmìlà ní kí ó mú àdó àrìkú,
Nítorí wípé kí ó bá pẹ́ láyé.
Ọ̀rúnmìlà tún ṣí, Ó lọ́ pé àwọn ìyàwó rẹ̀;
látí bá tún gbá àmọ̀ràn ẹnu wọn wò,
Ìgbá tí àwọn ìyàwọ́ rẹ̀ dé;
Wọ́n ní kí ó mú àdó ọmọ,
Nítorí wípé, ki àwọn bá bímọ púpọ̀;
Ọ̀rúnmìlà tún ṣí, Ó ní kí wọ́n lọ́ pé àwọn àbúrò òún wá,
láti gbá àmọ̀ràn lẹ́nu àwọn yẹn náà.
Àwọn àbúrò rẹ̀ ní kí ó mú àdó owó,
Nítorí wípé, tí ó bá ṣé bẹ́ẹ̀, ìdílé àwọn kò ní kúṣẹ̀ẹ̀,
Ọ̀rúnmìlà wá ní kí wọ́n lọ́ pe ọ̀rẹ́ òún wá,
Èṣù sí ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí, nígbá tí Èṣú dé;
Ó kẹ́jọ́, ó rò fún-un.
Ó wá bèèrè irú àdó tí ó yẹ kí òún mú,
Èṣù wá bèérè lọ́wọ́ Ọ̀rúnmìlà báyìí wípé;
Àwọn ọmọ rẹ̀ nkọ?
Irú àdó wo ni wọ́n ní kí o mú;
Ó ní àdó àrìkú ni,
Èṣù ní kí ó má mú.
Nítori wípé kò sí àwáyé ìkú.
Èṣù ní àwọn ìyàwó rẹ nkọ́,
Àdó kínnì wọ́n ni kí ó mú?
Ó ní wọ́n ní kí òún mú àdó ọmọ,
Èṣù ní kí ó má mú, nítorí ó tí bímọ;
Èṣù tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wípé,
Àwọn àbúrò rẹ nkọ́?
Àdó kíni wọ́n ní kí ó mú,
Ó ní àdó owó ni.
Nítorí wípé tí òún bádi olówó,
òún yóò yọ́ ìṣẹ́ lára àwọn ẹbí òún,
Èṣù ní kí ó má mú àdó owó,
Ọ̀rúnmìlà wá bèèrè lọ́wọ́
Èṣù irú àdó wó ní ó yẹ́ kí òún mú;
Èṣù dá lòhùn wípé, kí ó mú àdó sùúrù,
Nítorí wípé, sùúrù Ọ̀rúnmìlà kò tó,
Àti wípé, tí ó bá mú àdó sùùrù,
Gbogbo àdó tí ó kù yẹn tírẹ̀ ni wọn yóò jẹ́
Ọ̀rúnmìlà bá gbá àmọ̀ràn Èṣù,
Ó mú àdó sùùrù;
Ó kó mẹ́ta èyí tí ó kú fún igún;
Inú àwọn ọmọ, ìyàwò àtí ọmọ Ọ̀rúnmìlá
Kò dùn sí àdó tí ó mú,
igún bá nkó àwọn àdó mẹ́ta yìí ó lọ.
Nígbà tí igún rìn díẹ̀,
Owó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ wipe,
Níbo ní sùúrù wà?
Igún dá a lóùn wípé, ó wá nílé Ọ̀rúnmìlà,
Owo fún igún lésì, wípé òún nlọ bá sùùrù.
Igún ni irọ́ o,
À fi kí ó bá mí dé ọ̀dọ̀ Elédùnmarè.
Owo dá igún lóùn wípé,
Ibì ti sùùrù bá wà ni òún náà máa nwà.
Nígbà tí igún máa ri,
Owo tí fò kúrò lọ́wọ́ rẹ̀;
Ó tí lọ bá sùùrù nílé Ọ̀rúnmìlà
Ọmọ náà tún ṣí ó bèèrè sùùrù lọ́wọ́ igún
Igún da lóùn wípé, o wá nílé Ọ̀rúnmìlà
Ọmọ ní, ibi tí sùùrù bá wá,
ni òún náà máa nwà o;
Ọmọ ṣí ó lọ bá sùùrù nílé Ọ̀rúnmìlà.
Àrìkú náà tún bèèrè lọ́wọ́ igún,
Ó ní níbo ni sùùrù wà?
Igún dá lóùn wípé, ó wà nílé Ọ̀rúnmìlà.
Àrìkú ṣí ó lọ bá sùùrù nílé Ọ̀rúnmìlà.
Nígbá tí igún dé ọ̀run,
Elédùnmarè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀;
Àwọn mẹ́ta tí wọn kù.
Igún fún Elédùnmarè lésì wípé,
N ṣe ní óùn ní kí óùn wá sọ fún Elédúnmarè wípé;
Gbogbo wọ́n tí lọ bá sùùrù nílé Ọ̀rúnmìlá,
Ṣùgbọ́n òún fẹ̀ lọ kó wọn padà wá.
Elédúnmarè wá dá lóùn báyìí wípé;
Ẹní bá tí mú àdó sùùrù,
Ni ó ni àwọn tí ó kù o.
Ẹní bá ní sùùrù, á ní;
Ire àìkú, ire ọmọ, ire owó.
Ayé wá nyẹ Ọ̀rúnmìlà,
Wọ́n múu, wọ́n lọ fi jọba nílé kétu.
Owó sùn bò,
Ó n’ọ́la,Ó bímọ.
Ó tún wá fi àrìkú ṣe èrè jẹ.
Ó kọ́lé yíká gbogbo ayé,
Ó wá gun ẹṣin, Ó nkọ́rin báyìí:
Mo tí gba àdó owó o
Mo gbá tí ọmọ
Mo gbá tí àrìkú
Mo gbá tí sùùrù o
Ó njó, ó nyọ̀,
Ó nyin aláwo rẹ̀;
Ó tún nyin aláwo rẹ̀,
Ó tún nyin Èṣù ọ̀rẹ̀ rẹ̀.
Source: SàlámÌ, S. and RIBEIRO, I.: Exu e a ordem do universo. São Paulo, Editora Oduduwa, 2011.